Jobu 32:6-14
6
Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé, “Ọmọdé ni èmi, àgbà sì ní ẹ̀yin; ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró, mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
7
Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
8
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
9
Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
10
“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
11
Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín; èmi fetísí àròyé yín, nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;
12
àní, mo fiyèsí yín tinútinú. Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́; tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
13
Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí; Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’
14
Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.
Settings