Jobu 32:15-22
15
“Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́, wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
16
Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.
17
Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.
18
Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.
19
Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.
20
Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí, èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.
21
Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.
22
Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.
Settings