Jeremiah 6:26
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 26 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
23
Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀, wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú. Wọ́n ń hó bí omi Òkun, bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ; wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”
24
Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí obìnrin tí ń rọbí.
25
Má ṣe jáde lọ sí orí pápá tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà, ìpayà sì wà níbi gbogbo.
26
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.
27
“Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.
28
Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.
29
Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan, kí ó lè yọ́ òjé, ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán; a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.
Settings