Jeremiah 6:22
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 22 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
19
Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èso ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.
20
Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá, tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré? Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ọrẹ yín kò sì wù mí.”
21
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Àwọn baba àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n, àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”
22
Báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá, a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde láti òpin ayé wá.
23
Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀, wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú. Wọ́n ń hó bí omi Òkun, bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ; wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”
24
Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí obìnrin tí ń rọbí.
25
Má ṣe jáde lọ sí orí pápá tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà, ìpayà sì wà níbi gbogbo.
Settings