Jeremiah 51:1-13
1
Ohùn ti Olúwa wí nìyìí: “Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai,
2
Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo; wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.
3
Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀, jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀. Má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí; pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
4
Gbogbo wọn ni yóò ṣubú ní Babeli, tí wọn yóò sì fi ara pa yánnayànna ní òpópónà.
5
Nítorí pé Juda àti Israẹli ni Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun, kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.
6
“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí; yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
7
Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa; ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí. Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.
8
Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́. Ẹ hu fun un! Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ, bóyá yóò le wo ọ́ sàn.
9
“ ‘À bá ti wo Babeli sàn, ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀, kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè, ó ga àní títí dé òfúrufú.’
10
“ ‘Olúwa ti dá wa láre, wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa ti ṣe.’
11
“Ṣe ọfà rẹ ní mímú, mú àpáta! Olúwa ti ru ọba Media sókè, nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run. Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
12
Gbé àsíá sókè sí odi Babeli! Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí, ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri, ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́ Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde, òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.
13
Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!
Settings