Jeremiah 50:21-32
21
“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn tí ó ń gbé ní Pekodi. Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,” ni Olúwa wí, “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.
22
Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.
23
Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó, lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé! Báwo ní Babeli ti di ahoro ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
24
Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
25
Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.
26
Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo, sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀, ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà, kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.
27
Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ, jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n! Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé, àkókò ìbẹ̀wò wọn.
28
Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá, sì sọ ní Sioni, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
29
“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli, ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga sí Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
30
Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.
31
“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “nítorí ọjọ́ rẹ ti dé, àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.
32
Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.”
Settings