Jeremiah 49:34-39
34
Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.
35
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.
36
Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lòdì sí Elamu. Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé, kò sí orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.
37
Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn, àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn, Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, àní, ìbínú gbígbóná mi,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.
38
Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,” báyìí ni Olúwa wí.
39
“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,” báyìí ni Olúwa wí.
Settings