Jeremiah 49:16-22
16
Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.
17
“Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ.
18
Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní Olúwa wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.
19
“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
20
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Edomu, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde; pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
21
Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn, a ó gbọ́ igbe wọn ní Òkun pupa.
22
Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀, yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.
Settings