Skip to content
Jeremiah 41:1-10

Jeremiah 41:1-10

1
Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa.
2
Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà.
3
Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.
4
Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀,
5
àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa.
6
Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah jáde kúrò láti Mispa láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sọkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu.”
7
Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ihò kan.
8
Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Iṣmaeli pé, “Má ṣe pa wá! Àwa ní ọkà àti barle, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yòókù.
9
Nísinsin yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Gedaliah sí ni ọba Asa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí ọba Baaṣa ti Israẹli. Iṣmaeli ọmọ Netaniah sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.
10
Iṣmaeli sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mispa nígbèkùn, ọmọbìnrin ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tókù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti fi yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ṣe olórí. Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ammoni.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options