Skip to content
Jeremiah 34:3-7

Jeremiah 34:3-7

3
Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí ọba Babeli pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Babeli.
4
“ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekiah ọba Juda. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú;
5
ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ”
6
Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu.
7
Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options