Skip to content
Jeremiah 22:1-9

Jeremiah 22:1-9

1
Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin ọba Juda, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀:
2
‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ ọba Juda, tí ó jókòó ní ìtẹ́ Dafidi, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.
3
Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.
4
Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
5
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”
6
Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.
7
Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀, wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀, wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.
8
“Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’
9
Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options