Jeremiah 13:1-13
1
Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.”
2
Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.
3
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì,
4
“Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.”
5
Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.
6
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.”
7
Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.
8
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
9
“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu.
10
Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun.
11
Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’
12
“Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’
13
Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu.
Settings