Skip to content
Isaiah 66:7-14

Isaiah 66:7-14

7
“Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin.
8
Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
9
Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí.
10
“Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀; ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11
Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára, ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
12
Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
13
Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
14
Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options