Skip to content
Isaiah 63:11-19

Isaiah 63:11-19

11
Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì, àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀ níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já, pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀? Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,
12
ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀ láti wà ní apá ọ̀tún Mose, ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn, láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,
13
ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já? Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀;
14
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko, a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa. Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.
15
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo. Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà? Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a ti mú kúrò níwájú wa.
16
Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe; ìwọ, Olúwa ni Baba wa, Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.
17
Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ? Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ.
18
Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.
19
Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì; ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jẹ ọba lé wọn lórí, a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options