Skip to content
Isaiah 43:14-21

Isaiah 43:14-21

14
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli: “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli, nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15
Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”
16
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun, ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
17
ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
18
“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19
Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsin yìí, ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20
Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21
àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options