Isaiah 41:10-14
10
Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.
11
“Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.
12
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn. Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́ yóò dàbí ohun tí kò sí.
13
Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.
14
Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
Settings