Isaiah 24:10-23
10
Ìlú tí a run ti dahoro, ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11
Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12
Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
13
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán.
14
Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀; láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo ọláńlá Olúwa.
15
Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa; gbé orúkọ Olúwa ga, àní Ọlọ́run Israẹli, ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun.
16
Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin; “Ògo ni fún olódodo n nì.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé! “Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17
Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́, ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà yóò ṣubú sínú ihò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú. Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19
Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20
Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́; ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.
21
Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
22
A ó sì kó wọn jọ pọ̀, gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò, a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú, a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
23
A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn; nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu, àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings