Isaiah 2:6-22
6
Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ìwọ ilé Jakọbu. Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá, wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini, wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.
7
Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
8
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
9
Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀, má ṣe dáríjì wọ́n.
10
Wọ inú àpáta lọ, fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀ kúrò nínú ìpayà Olúwa, àti ògo ọláńlá rẹ̀!
11
Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.
12
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),
13
nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó àti gbogbo óákù Baṣani,
14
nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá àti àwọn òkè kéékèèké,
15
fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò,
16
fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
17
Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
18
gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.
19
Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta àti sínú ihò ilẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
20
Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán.
21
Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta àti sínú ihò pàlàpálá àpáta kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
22
Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́, èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀. Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings