Skip to content
Hosea 7:8-16

Hosea 7:8-16

8
“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.
9
Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀. Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i.
10
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
11
“Efraimu dàbí àdàbà tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí tó sì tún ń padà lọ si Asiria.
12
Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.
13
Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.
14
Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15
Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16
Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo; wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́. Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí ìrunú ahọ́n wọn. Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options