Hosea 5:1-7
1
“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín. Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori.
2
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
3
mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu Israẹli kò sì pamọ́ fún mi Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè Israẹli sì ti díbàjẹ́.
4
“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn, wọn kò sì mọ Olúwa.
5
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn; àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
6
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa, wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
7
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ. Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.
Settings