Skip to content
Hosea 4:15-19

Hosea 4:15-19

15
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
16
Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù. Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
17
Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!
18
Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán, wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè. Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
19
Ìjì ni yóò gbá wọn lọ. Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options