Skip to content
Heberu 12:1-18

Heberu 12:1-18

1
Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,
2
kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.
3
Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìsọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
4
Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín.
5
Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé, “Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí,
6
nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí, a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”
7
Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí, Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí?
8
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ.
9
Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè?
10
Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n Òun tọ́ wa fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀.
11
Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12
Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera,
13
“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.
14
Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa.
15
Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí gbòǹgbò ìkorò kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́.
16
Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀.
17
Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi.
18
Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options