Gẹnẹsisi 47:13-26
13
Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Ejibiti àti ilẹ̀ Kenaani gbẹ nítorí ìyàn náà.
14
Josẹfu gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti àti Kenaani ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Farao.
15
Nígbà tí owó wọn tán pátápátá ní Ejibiti àti Kenaani, gbogbo Ejibiti wá bá Josẹfu, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tán.”
16
Josẹfu wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.”
17
Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹṣin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn wọn.
18
Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀lé, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tókù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa.
19
Èéṣe tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkára wa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbèkùn Farao. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.”
20
Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao,
21
Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì.
22
Ṣùgbọ́n ṣá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Farao, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Farao ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn.
23
Josẹfu wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ́n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Farao, irúgbìn rèé, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà.
24
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìre oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdákan nínú ìdámárùn-ún rẹ̀ fún Farao. Ẹ le pa ìdámẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.”
25
Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Farao.”
26
Nítorí náà Josẹfu sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Ejibiti, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òní olónìí pé, ìdákan nínú ìdámárùn-ún ìre oko jẹ́ ti Farao, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Farao.
Settings