Esekiẹli 36:24-38
24
“ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀-èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín.
25
Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin.
26
Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín.
27
Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́.
28
Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.
29
Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín.
30
Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn.
31
Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu.
32
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!
33
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀.
34
Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́.
35
Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.”
36
Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’
37
“Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí àgùntàn,
38
kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.”
Settings