Skip to content
Esekiẹli 36:16-23

Esekiẹli 36:16-23

16
Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
17
“Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi.
18
Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́.
19
Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn.
20
Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’
21
Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ.
22
“Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ.
23
Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options