Eksodu 9:28-35
28
Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”
29
Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.
30
Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run.”
31
(A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi.
32
Alikama àti ọkà ni a kò lù bolẹ̀, nítorí tí wọ́n kò tí ì dàgbà.)
33
Nígbà náà ni Mose jáde kúrò ni iwájú Farao, ó kúrò ni àárín ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.
34
Nígbà tí Farao rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣì sé àyà wọn le.
35
Àyà Farao sì le, bẹ́ẹ̀ ni kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, bí Olúwa ti sọ láti ẹnu Mose.
Settings