Eksodu 19:22-25
22
Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá síwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọlù wọ́n.”
23
Mose wí fún Olúwa pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Sinai, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”
24
Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”
25
Mose sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí Olúwa wí fún wọn.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings