Skip to content
Esteri 6:4-11

Esteri 6:4-11

4
Ọba wí pé, “Ta ni ó wà nínú àgbàlá?” Nísinsin yìí, Hamani ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ àgbàlá ìta ààfin ni láti sọ fún ọba nípa síso Mordekai lórí igi tí ó ti rì fún un.
5
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dáhùn pé, “Hamani ni ó wà níbẹ̀ ó dúró sí inú àgbàlá.” Ọba pàṣẹ pé, “Ẹ mú un wọlé wá.”
6
Nígbà tí Hamani wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?” Nísinsin yìí Hamani sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, “Ta ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?”
7
Nítorí náà Hamani dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá,
8
jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí.
9
Jẹ́ kí a fi aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn máa kéde níwájú rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ”
10
Ọba pàṣẹ fún Hamani pé, “Lọ lẹ́sẹ̀kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Mordekai ará a Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.”
11
Bẹ́ẹ̀ ni Hamani ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Mordekai, Mordekai sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájú rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options