Skip to content
Esteri 4:4-12

Esteri Kọ́ Nípa Ìṣòro Náà

Esteri 4:4-12
4
Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Esteri wá, wọ́n sọ nípa Mordekai fún un, ayaba sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. Ó fi aṣọ ránṣẹ́ sí i kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n.
5
Nígbà náà ni Esteri pe Hataki, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Mordekai àti ohun tí ó ṣe é.
6
Bẹ́ẹ̀ ni Hataki jáde lọ bá Mordekai ní ìta gbangba ìlú níwájú ẹnu-ọ̀nà ọba.
7
Mordekai sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hamani ti ṣe ìpinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù.
8
Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun wọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Susa, láti fihan Esteri kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún un, ó sì sọ fún un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ síwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀.
9
Hataki padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Esteri ohun tí Mordekai sọ.
10
Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai,
11
“Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”
12
Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai,
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options