Skip to content
Daniẹli 11:6-14

Daniẹli 11:6-14

6
Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.
7
“Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọlu ogun ọba àríwá, yóò sì wó odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.
8
Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.
9
Nígbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, gúúsù, ṣùgbọ́n yóò padà sí Orílẹ̀-èdè, òun fúnra rẹ̀.
10
Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.
11
“Nígbà náà ni ọba gúúsù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ-ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba gúúsù yóò borí i wọn.
12
Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba gúúsù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa síbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun.
13
Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára.
14
“Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba gúúsù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options