Skip to content
Kolose 2:1-7

Kolose 2:1-7

1
Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodikea àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí.
2
Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnra rẹ̀.
3
Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí.
4
Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma ba à fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín ṣìnà.
5
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsi ètò yín àti bí ìdúró ṣinṣin yín nínú Kristi ti rí.
6
Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.
7
Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options