Kolose 1:24-29
24
Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ.
25
Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ.
26
Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́.
27
Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín.
28
Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kristi.
29
Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń ṣiṣẹ́ nínú mi.
Settings