Ìṣe àwọn Aposteli 27:2-7
2
Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.
3
Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
4
Nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, a lọ lẹ́bàá Saipurọsi, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì.
5
Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti Pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia.
6
Níbẹ̀ ni balógun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-òkun Alekisandiria kan, ti ń lọ sí Itali; ó sì fi wa sínú rẹ̀.
7
Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni.
Settings