Ìṣe àwọn Aposteli 27:13-20
13
Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ.
14
Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà.
15
Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ.
16
Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò.
17
Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri.
18
Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀.
19
Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù.
20
Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.
Settings