Ìṣe àwọn Aposteli 19:11-16
11
Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu,
12
tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.
13
Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.”
14
Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù.
15
Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”
16
Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.
Settings