Ìṣe àwọn Aposteli 19:11-20
11
Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu,
12
tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.
13
Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.”
14
Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù.
15
Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”
16
Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.
17
Ìròyìn yìí sì di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Giriki pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Efesu; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jesu Olúwa ga.
18
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn.
19
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń ṣe alálúpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣírò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) ìwọ̀n fàdákà.
20
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbèrú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.
Settings