Ìṣe àwọn Aposteli 17:25-30
25
Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.
26
Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;
27
Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa.
28
Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa, bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’
29
“Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀.
30
Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà.
Settings