2 Samuẹli 23:1
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 1 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé,
2
“Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi.
3
Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
4
Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’
Settings