2 Samuẹli 11:1-5
1
Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dafidi sì rán Joabu, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Israẹli; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ammoni, wọ́n sì dó ti Rabba. Dafidi sì jókòó ní Jerusalẹmu.
2
Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò.
3
Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, “Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti.”
4
Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀, nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
5
Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti lóyún.”
Settings