2 Ọba 19:14-19
14
Hesekiah gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ síwájú Olúwa.
15
Hesekiah gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ń gbé ní àárín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
16
Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Sennakeribu tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.
17
“Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Asiria ti pa orílẹ̀-èdè wọ̀nyí run àti ilẹ̀ wọn.
18
Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn.
19
Nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkan ṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”
Settings