2 Ọba 18:1-7
1
Ní ọdún kẹta Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli, Hesekiah ọmọ Ahasi ọba Juda bẹ̀rẹ̀ ìjọba.
2
Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó ti di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Abijah ọmọbìnrin Sekariah.
3
Ó sì ṣe ohun tí ó dára níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ Dafidi ti ṣe.
4
Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ àwọn ère òkúta, ó sì gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀, ó sì fọ́ ejò idẹ tí Mose ti ṣe náà túútúú, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Nehuṣitani.)
5
Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀.
6
Ó súnmọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mose.
7
Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín.
Settings