Skip to content
2 Kronika 31:16-21

2 Kronika 31:16-21

16
Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbí ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbà wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn.
17
Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn.
18
Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlú tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.
19
Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Aaroni, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàrín wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Lefi.
20
Èyí ni Hesekiah ṣe jákèjádò Juda, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
21
Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé ní ti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.

Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.

Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options