2 Kronika 28:5-8
5
Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Siria lọ́wọ́. Àwọn ará Siria sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Damasku. Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Israẹli pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbèkùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.
6
Ní ọjọ́ kan Peka, ọmọ Remaliah, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àwọn ọmọ-ogun ní Juda nítorí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀.
7
Sikri àti Efraimu alágbára sì pa Maaseiah ọmọ ọba, Aṣrikamu ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elkana igbákejì ọba.
8
Àwọn ọmọ Israẹli sì kó ní ìgbèkùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Samaria.
Settings