2 Kronika 20:21-25
21
Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí Olúwa àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé, “Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.”
22
Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, Olúwa rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n.
23
Àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Seiri láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin láti òkè Seiri, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.
24
Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá.
25
Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.
Settings