1 Samuẹli 6:1-9
1
Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Filistini fún oṣù méje,
2
àwọn ará Filistini pe àwọn àlùfáà, àti àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí ààyè rẹ̀.”
3
Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti àwọn ọmọ Israẹli padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”
4
Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?” Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín.
5
Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli. Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín.
6
Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?
7
“Nísinsin yìí ẹ pèsè kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fi ọmú fún ọmọ, èyí tí a kò tí ì gba àjàgà sí ọrùn rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so.
8
Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ,
9
ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọlù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni.”
Settings