1 Samuẹli 22:9-19
9
Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu.
10
Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”
11
Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba.
12
Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.” Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.”
13
Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”
14
Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ.
15
Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.”
16
Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”
17
Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.
18
Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu.
19
Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.
Settings