1 Samuẹli 18:20-27
20
Nísinsin yìí ọmọbìnrin Saulu Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, nígbà tí wọ́n sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn.
21
Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ ìkẹ́kùn fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Filistini lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Dafidi pé, “Nísinsin yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna án mi.”
22
Saulu pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dafidi ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsin yìí jẹ́ àna ọba.’ ”
23
Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dafidi. Ṣùgbọ́n Dafidi wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”
24
Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Saulu sọ fún un ohun tí Dafidi sọ,
25
Saulu dáhùn pé, “Sọ fún Dafidi pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn-ún Filistini lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ ” Èrò Saulu ni wí pé kí Dafidi ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Filistini.
26
Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá,
27
Dafidi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Filistini. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó ba à lè jẹ́ àna ọba. Saulu sì fi ọmọ obìnrin Mikali fún un ní aya.
Settings