1 Samuẹli 10:5-10
5
“Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.
6
Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀.
7
Bí ìwọ bá ti rí àmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.
8
“Lọ ṣáájú mi sí Gilgali. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”
9
Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà.
10
Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Settings