Fò sí àkóónú
1 Peteru 4:1-6

Dá ẹ̀ṣẹ̀ dúró nípasẹ̀ ìjìyà

1 Peteru 4:1-6
1
Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
2
Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.
3
Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.
4
Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.
5
Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú.
6
Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìyìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options