Skip to content
1 Peteru 4:1-11

1 Peteru 4:1-11

1
Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
2
Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.
3
Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.
4
Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.
5
Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú.
6
Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìyìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.
7
Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà.
8
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín, nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
9
Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú.
10
Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
11
Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options